IFÁ jẹ́ ohun Ọgbọ́n Ọlọ́run Olódùmarè.



 Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé Olódùmarè ló rán Ifá wá láti òde ọ̀run latí wá fi Ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé ṣe. Ọgbọ́n, ìmọ̀, àti òye tí Olódùmarè fi fún Ifá ló fún Ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ní ilẹ̀ Yorùbá. “A-kéré-finú-ṣọgbọ́n” ni oríkì Ifá. Ọ̀rúnmìlà ni aaju Ifá nipa ohun gbogbo bi ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni li aye. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni wípé ní ìgbà kan rí, Ọ̀rúnmìlà gbé òde-ayé fún ìgbà pípẹ́ kí o tó padà lọ sí Ọ̀rùn. Ní ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà fi wà ní ilé ayé, ó gbé Ilé-Ifẹ̀ fún ìgbà péréte. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà fi wà láyé yìí náà, a tún máa lọ sí òde ọ̀run lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí Olódùmarè bá pèé láti wá fi Ọgbọ́n rẹ̀ bá òun tún òde-ọ̀rùn ṣe. Nítorí náà gbáyégbọ́run ni Ọ̀rúnmìlà Ifá ńṣe.

Ìtàn sọ fún wa wípé ọmọ mẹ́jọ ni Ọ̀rúnmìlà bí nígbà tí ó wà láyé, nígbà tí ó di ọjọ́ kan ti Ọ̀rúnmìlà ńṣe ọdún ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ yìí tíí ṣe àbíkẹ́hìn pátápátá bá ṣe àfójúdi sí Ọ̀rúnmìlà, ni Ọ̀rúnmìlà bá bínú fi ayé sílẹ̀ lọ sí òde Ọrun. Ni Ọ̀rúnmìlà  ìfá bá relé olókun kòdé mọ́. Ó lẹ́ni tí ẹ bá rí, ẹ ṣá máa pè ní baba”. Ṣùgbọ́n Ọ̀rúnmìlà fún àwọn ọmọ rẹ̀ méjẹ̀ẹ̀jọ náà ní ìkín mẹ́rìndínlógún ó ní bẹ́ ẹ délé bẹ́ẹ bá fówóó ní, ẹni tẹ̀ ẹ́ maa bi nù u.

ìkín ifá mẹ́rìndínlógún náà ni à ń lò lòníí láti bèèrè nǹkan lọ́wọ́ Ifá.


Comentários

Postagens mais visitadas deste blog

O Odu Ifá Eji Ogbe

Eji Ogbe tabi Ogbe Meji, Bàbá Odu Ifá