Eji Ogbe tabi Ogbe Meji, Bàbá Odu Ifá

 


Mo ki yin, olólùfẹ́ èdè ati Àà Yorùbá kaakiri ni orílẹ̀-èdè lagbaye.

Orúkọ tèmi ni Adelson Adéwalé de Brito ti ọpọlọ́pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Mawo Adelson. Olukọ̀ Àgbà èdè ati àṣà Ànàgó ni ìlú Salvador. Olu-ìlú ipinlẹ̀ Baííà ni orílẹ̀-èdè Brasili ìlú Salvador lo n ṣe. Mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbádura si Ọlọ́run pe ki ìjọba rẹ̀ de laibikita ìsìn olukaluku wọn nitori wipe Ọlọrun nìkan ṣoṣo wa, lẹ́da naa gbogbo ènìyàn ati lẹ́da gbogbo ohun to wa ninu ilè Aye. Olùgbàlà wa kí á tó dá ayé, ati nisinsinyii ati títí ayé ainipẹkun, lailai aẹ́. AMIN.

Èjì Ogbè tabi Ogbe Meji, Odu Kini Ifa n ni loni wipe:

oju kò kan mi

emi kò kan ju

ni o difa fún ero pese

ti ń l ṣe ọk ìgbín

ìgbín ńwá ọk

ero pese ńwá ìyàwó

àwọn n mejeeji wá l si ilé alawo ni otootọ

ero pese wá bèèrè lọ́wọ́ Ifa wipe njẹ́ oun le ni aya

ìgbín naa bèèrè lọ́wọ́ alawo rẹ̀ wipe ńjẹ́ oun le ni ọk

awo ń babalawo awo mejeeji sọ̀ fún wọ́n wípè

ki wọ́n lọ rubọ, ki wọ́n si tún lo ni ọpọ́lọp suuru

wipe ati ọk ati aya yio pade ara wọ́n

bayi ni olukaluku wọ́n ba lọ ru ẹbọ ti babalawo wọ́n ka fún wọ́n nitori òtítọ́ ni wọ́n lọ si ilé alawo

ti o si jẹ́ odu kan naa ni o yio fún awo ń mejeeji lai mọ̀ ara wọ́n ri

bi wọ́n ṣe rubọ tan ni ero pese pade ìgbín

ni wọ́n ba sọ̀rọ̀ ti ọ̀rọ̀ wọ́n ye ara wọ́n

ti wọ́n wa gbe ara ni ìyàwó

ni nkan wọ́n ba bèèrè si ni dara si

ti ọ̀rọ̀ wọ́n ba dero ti ayo idunun owó

alaafia ati ire gbogbo bẹ̀rẹ̀ si ni to wọ́n lọ́wọ́

ni wọ́n wa njo ni wọ́n wa ńyọ̀.


Comentários

Postagens mais visitadas deste blog

O Odu Ifá Eji Ogbe

IFÁ jẹ́ ohun Ọgbọ́n Ọlọ́run Olódùmarè.